Birthday Poem

Eku Ojo Ibi Maami

 

Ni gba ti moronu jinle

Ti mo wadi bi ile aye seri

mo koko se wadi eniti ogbe mi wa saye.

 

Ni gba ti mo ro nu jinle

Ti mo se asaro nkan ti hun o da lojo ola,

mo ronu kan eniti o gbe mi wa ile aye.

 

Iyaa mi,

Maami,

Mama mi,

Ko si eniti o le dabi iya funmi afi eyin.

Gbogbo oun ti eti se funmi

Ko to simi.

 

Ife ti e da lemi lori

ko lafi we.

 

E jiya nitorimi

Egba awe nitorimi

E saisun nitorimi

E gbadura nitorimi.

 

Iyami

Okan yin ma bale

E o ni kaba mo lorimi

 

Iya mi

Abiyamo bi tire sowon.

Iya oninure

Iya mi, iyawo baba mi

Iya mi, iya awon aburo mi.

Iya mi, iya  iya awon omo mi.

Oku ojo ibi o.

Emi re o gun.

 

Aladura mi

Oludamoran mi.

Aseyi samodun o

Igba odun odun kan

Aseyi samodun o

ninu ifokan bale ati oro.

 

Iya mi

Monifeere lopolopo.

Oku Ojo Ibi.

 

 

You Might Also Like

No Comments

Leave a Reply